Mo juba Oba, Mo juba Oba Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun Mo juba Oba Mo juba Oba, Mo juba Oba Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun Mo Ju Ba Iba Eledumare, Oba to ni gbogbo aye Eni nla ti mbe lori ite titi lai lai lai Emi mi b'ola fun O o lati ogbun iseda mi Mo yi ka otun, mo yi t'osi mo ba ruburubu F'Eni naa Alaponlejulo, Eni Ayeraye Iwo lo ti mbe, Iwo loo si ma be, Leyin Re, ko si mo, Oba titi lai Mo sin O, Mo sin O, Mo sin O Lat'ogbun emi mi Eni naa, Oba naa, Oluwosan, Alaanu Gbogbo iseda ati emi, a n b'ola fun O Mo juba Oba, Mo juba Oba Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun Mo juba Oba Iwo ni Oba ti o le pa'poda lailai Oba to ti wa ti o si ma be tititi Aye mi yio ma fi ibukun fun oruko Re Ileke ola, Ipile oye, opin gbogbo ola Gbogbo ise Re ni o ma yin O, a n pe O lOba Iwo ni Alaanu to f'ebun se mi loso O tun fi ogo de ebun to fun mi lade Odo Re naa ni gbogbo ogo naa n pada si Oluwa Eni naa, Oba naa, Oluwosan, Alaanu Gbogbo iseda ati emi, a n b'ola fun O Gbogbo ise Re ati emi o A n b'ola fun O Awon ohun taa ri at'awon ta o ri, won n b'ola fun O A n b'ola fun O Loke orun lohun, lagbedemeji ile t'a n te, ogo ni f'ooko Re A n b'ola fun O Iwo ni O ni ike to po, Olola to po, Alaanu to po A n b'ola fun O Ko si ede naa ni gbogbo aye ti iro ogo Re kii buyo Oluwa A n b'ola fun O Hiho okun n bu ola fun O, Osa naa n b'ola fun O, gbogbo ise. A n b'ola fun O Gbogbo ede, gbogbo ijoba, lo n wariri fun Oruko Re A n b'ola fun O Gbogbo ise Re ati emi A n b'ola fun O